Ìtàn mánigbàgbé: bode thomas ní ọpọlọ pípé, ó jẹ́ aṣaájú àmọ́ ó ní inú fùfù - bbc news yorùbá

Play all audios:

ÌTÀN MÁNIGBÀGBÉ: BODE THOMAS NÍ ỌPỌLỌ PÍPÉ, Ó JẸ́ AṢAÁJÚ ÀMỌ́ Ó NÍ INÚ FÙFÙ 16 Sẹ́rẹ́ 2020 Ìgbà tí a ṣe àfíkun gbẹ̀yìn 19 Sẹ́rẹ́ 2020 ORUKỌ ỌMỌỌBA ALFRED OLABODE AKANNI THOMAS, TI GBOGBO
EEYAN MỌ SI OLABODE THOMAS, LEE MA NITUMỌ MỌ NIWAJU AWỌN ỌDỌ IWOYI AMỌ ARUGBO RẸ TI SE OGE RI NILẸ YII, EKISA RẸ SI TI LO IGBA RI. Lootọ orukọ Olabode Thomas lee ma jẹ ki awọn eeyan ranti
adugbo kan ti wọn fi sọri rẹ ni agbegbe Surulere nipinlẹ Eko, amọ ohun ribiribi to se nile aye ko gbọdọ parẹ. ÀWỌN IRÒYIN TÌ Ẹ LEÈ NÍ ÌFẸ̀ SÍÍ: * Dele, ọmọdé tó ń fi iná ẹ̀rọ ATM ṣe iṣẹ́
àmurelé sọ ìdí tó fi kára mọ́ ẹ̀kọ́ rẹ̀ fún BBC Yorùbá * Elédùmarè ló rán mi sí gbogbo Ọba Yorùbá - Oluwo * 'Ẹ jọ̀ọ́, a ò fẹ́ gbọ́ òfófó ìròyìn mọ́ pé àbúrò mi gún bàbá àti ìyá mi pa, ó
ti tó gẹ́!' * Torí ǹkan oṣù, Iléèwé pàṣẹ kí àwọn akẹ́kọ̀ọ́bìnrin tú síhòhò * Bí orí ṣe yọ akẹ́kọ̀ọ́ Cameroon kan tó bọ́ lọ́wọ́ Coronavirus rèé Bi Olabode Thomas ko tilẹ dagba tabi
darugbo ko to jade laye, nitori ko lo ju ọdun mẹrinlelọgbọn lọ, to fi tẹri gbasọ, sibẹ a ko gbọdọ gbagbe akanda ọmọ Yoruba yii, tori ipa to ko si idagbasoke iran Yoruba ati Naijiria lapapọ.
Gẹgẹ baa ti ri ka loju opo ikansiraẹni lori ayelujara, Wikipedia, awọn ohun to yẹ ka mọ nipa Olabode Thomas ree, tori bi onirese rẹ ko ba fingba mọ, awọn eyi to ti fin silẹ ko lee parun. TA
NI OLABODE THOMAS, IRU IGBE AYE WO LO GBE? * Osu Kẹwaa, ọdun 1919 ni Olabode Thomas de ile aye, iyẹn lẹyin ọdun marun un ti baba Naijiria, Lord Lugard so ẹkun ariwa pọ mọ guusu, ti wọn si di
Naijiria kansoso * Olokoowo to gbajugbaja nilu Eko ni Andrew Thomas ati iyawo rẹ ti wọn jẹ obi Bode Thomas, ilu Ọyọ Alaafin ni wọn si ti wa sisẹ aje nilu Eko. * Koda, a si lee ni idile
ọlọla ati olowo lo ti jade, ọmọ ti wọn fi ọla ati owo tọ lati kekere ni Bode Thomas. * Bode Thomas jẹ omiran ẹda, ẹni to ga, to si ṣigbọnlẹ bẹẹ, eyi to mu ki wọn fun ni orukọ inagijẹ
'Buldozer', bẹẹ si ni kii faaye gba ijakulẹ, to si maa n wa aseyọri ninu gbogbo ohun to ba dawọle * Ile ẹkọ girama CMS ti Samuel Ajayi Crowther da silẹ ni Bode Thomas lọ, to si
bẹrẹ isẹ lọgan to pari iwe mẹwaa rẹ bii akọwe nileesẹ Reluwe ilẹ wa * Nigba to di ọdun 1939, ni Bode Thomas morile ilu London lati lọ kọ ẹkọ nipa imọ ofin, to si di agbẹjọro, to si di
ojulowo lọya lọdun 1942, ko to pada wale lati wa da ileesẹ agbẹjọro tiẹ silẹ nilu Eko * Bode Thomas, Frederick Rotimi William ati Remilekun Fani Kayode ni wọn dijọ da ileesẹ naa silẹ, ti wọn
pe ni Thomas, Williams and Kayode law firm * Ọdun 1946 ni Bode Thomas di agbẹjọro fun ẹgbẹ Ọmọ Oduduwa, to si tun jẹ ọkan lara awọn eeyan to da ẹgbẹ oselu Ọlọpẹ, taa mọ si ẹgbẹ Awolowo,
Action Group silẹ O ṣójú mí kóró bí wọ́n ṣé fí àdó olóró pa Dele Giwa lọdún 1986- Soyinka Skip Èyítí A Ń Kà Jùlọ and continue reading ÈYÍTÍ A Ń KÀ JÙLỌ * Ìdálọ́lá fún Kudirat Abiola, àti
àwọn kókó mìí tó jẹyọ nínú ọ̀rọ̀ tí Aarẹ Tinubu sọ ní June 12 * Kí ló mú kí òkè Iya Mopo nílùú Igbeti máa ya lulẹ̀, tó tún n ṣí èèpo? Nnkan tí a mọ̀ rèé * Ọkọ̀ òfúrufú tó gbé èèyàn tó lé ní
200 já, iṣẹ́ ìdóòlà ẹ̀mí bẹ̀rẹ̀ * Ohun tó yẹ kí o mọ̀ nípa bí China ṣe fẹ́ fagilé owó orí tàríìfù lórí ọjà tó ń wọlé láti Africa End of Èyítí A Ń Kà Jùlọ Pius Adesanmi ní kò bá rọ́pò Wole
Soyinka tí kò bá kú - ọmọ Naijiríà Soyinka: Ọ̀pọ̀ ìgbà ni ayédèrú ìròyìn ti pa mí Wole Soyinka rèé láti kékeré * Ọdun 1949 ni Bode Thomas gba oye Balogun Oyo, eyi to lo lati fa oju awọn Ọba,
ijoye ati eeyan jankan-jankan wa sinu ẹgbẹ oselu Ọlọpẹ, ti ero oun ati Oloye Obafemi Awolowo si saAba maa n yatọ lasiko ti wọn ba n jiroro ninu ẹgbẹ. * Bode Thomas di Minisita feto
igbokegbodo ọkọ labẹ ofin Mcpherson lọdun 1951, to si n soju ẹkun iwọ oorun guusu Naijiria, ibẹ si lo ti n fọnrere fun agbekalẹ ijọba awa ara wa lorilẹ-ede yii , to fẹ ko bẹrẹ lọdun 1956 *
Nigba ti wahala suyọ lori ofin Mcpherson losu kẹta, ọdun 1953 ni Bode Thomas kọwe fi ipo minisita silẹ, amọ o pada wa di minisita fun isẹ ode lẹyin ipade apapọ lori atunse ofin to waye nilu
London * Itan fi ye wa pe bi Bode Thomas se jẹ ọlọpọlọ pipe ẹda to, naa LO NI ỌKAN GIGA TO, EYI TO MU KI IBASEPỌ OUN ATI AWỌN OLORI KAN MA GUN RARA, to fi mọ Ọlọla Ahmadu Beloo ati Alaafin
Adeyẹmi keji. * Bode Thomas jẹ oninu fufu tI KII PẸ BINU, KII PA ỌRỌ MỌRA, o maa n sọ tinu rẹ jade lai fẹ mọ ẹniti ọrọ naa yoo bi ninu, eyi to maa n mu ko di ọta ọpọ eeyan * Nibi ipade
igbimọ lọbalọba to waye lọdun 1953 eyi ti Bode Thomas jẹ alaga fun, la gbọ pe o ti yaju si ọba Adeniran Adeyẹmi, tii se baba Alaafin Lamidi Ọlayiwọla Adeyẹmi kẹta to wa lori oye bayii, to si
n sọrọ si ori ade naa pe ko dide duro lati yẹ oun si nigba ti oun wọle, gẹgẹ bi awọn Ọba alaye yoku to wa nikalẹ ti se * Iroyin kan ti ko fidi mulẹ, to n lọ lati atẹnudẹnu tun sọ pe ọrọ yii
bi Ọba Adeyẹmi ninu to bẹẹ, to si ni ki Bode Thomas maa gbo lọ pẹlu bo se n bu oun yii, lọjọ kejilelogun, osu Kọkanla lẹyin ipade ti Bode dele rẹ ni Yaba nilu Eko lati Ọyọ, lootọ lo ba n
gbo bii aja. * Wọn gbe Bode Thomas lọ silu Ijẹbu Igbo fun itọju, sugbọn nibẹ lo ti tẹri gbasọ lọjọ Kẹtalelogun, osu Kọkanla, ọdun 1953 * Bode Thomas fẹ iyawo, ti orukọ rẹ n jẹ Lucretia
Sobola Odunsi, to si bi ọpọ ọmọ. Lara wọn ni Ẹniọla ati Dapọ. Ọmọọba Alfred Olabode Akanni Thomas ku togo-togo, ko gbe ile aye lati da awọn ara to wa ninu rẹ nitori ọdun mẹrinlelọgbọn pere
lo se nile aye. Èyí ni bí ogun abẹ́lé Biafra ṣe bẹ̀rẹ̀ ní Nàìjíríà Ọ̀pọ̀ àwòrán tó ń ṣeni láàánú rèè nípa ogun abẹ́lé Nàíjíríà Ǹjẹ́ o mọ ipa tí ẹja Panla kó lásìkò ogun abẹ́lé Biafra? Ọta
ìbọn ogun Biafra ṣì wà lọ́rùn mi lẹ́yìn àádọ́ta ọdún tí ogun parí - Umar AWỌN ẸKỌ TI ITAN IGBE AYE BODE THOMAS KỌ WA: * Ẹkọ akọkọ ni pe A GBỌDỌ SE AMULO ỌPỌLỌ TI ỌLỌRUN FUN WA LATI FI MU
IDAGBASOKE BA AWUJỌ ati iran wa * Ẹkọ miran ti itan igbe aye Bode Thomas kọ wa tun ni lati MASE FI AAYE GBA IBINU TABI SỌRỌ ODI, paapaa si awọn eeyan to ju wa lọ. * Ikẹta ni pe a GBỌDỌ MAA
WA ỌRẸ KUN ỌRẸ NI, KII SE KA MAA WA ỌTỌ KUN ỌTA LẸNU ISẸ abi ni ilu abinibi wa * Itan igbe aye Bode Thomas tun kọ wa pe ninu gbogbo ohun ti a ba n se, KA FI SUURU KUN NITORI IBINU MAA n ba
nkan jẹ ni * O tun kọ wa pe ka maa sọ ẹnu wa, ẸNU LẸBỌ TORI ỌRỌ RERE LO N FA OBI LAPo, ọrọ buruku si lo n fa ida lakọ. A wa gbadura pe Ọba oke tẹ Alfred Olabode Akanni Thomas si afẹfẹ rere
nibayii to ti pe ọdun mẹtadinlaadọrin to ti jade laye. * Ṣo mọ̀ pé J.F Odunjo jẹ aṣòfin àti mínísítà nílẹ̀ yìí, yàtọ̀ sí pé ó jẹ́ òǹkọ̀wé? * Ìtàn Gbọnka àti Timi, akọni méjì tó borí Aláàfin
Ṣango * Òkè Idanre rèé tí odidi ìlú kan ló ń gbé lórí ẹ̀ * Lisabi Agbongbo Akala rèé, ẹni tó fi ìfẹ́, ìṣọ̀kan àti ìrẹ́pọ̀ gba ilẹ̀ Ẹ̀gbá lọ́wọ́ ìmúnisìn